Ìfihàn sí Life with Tioluwani
カートのアイテムが多すぎます
カートに追加できませんでした。
ウィッシュリストに追加できませんでした。
ほしい物リストの削除に失敗しました。
ポッドキャストのフォローに失敗しました
ポッドキャストのフォロー解除に失敗しました
-
ナレーター:
-
著者:
Ẹ káàbọ̀ sí Life with Tioluwani Podcast
Ọpẹ́ ńlá ni mo dá Ọlọ́run pé o wà níhìn-ín!
Pọdkásitì yìí wà láti tọ́ka sí àwọn ènìyàn sí Jésù Krístì àti láti tọ́ wọn sọ́nà nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ nípasẹ̀ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìfihàn yìí, mo ń pín ìrìn àjò tèmi ti bí mo ṣe pàdé Jésù, bí Ó ṣe yí ìgbésí ayé mi padà, àti ìdí tí mo fi gbàgbọ́ pé Ó ṣì ń yí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn padà títí di òní.
Mo fẹ́ fi ìpín mẹ́ta tí ẹ ó rí lórí pọdkásitì yìí mọ̀ yín:
The Believer Series:
Ìkéde Ìfẹ́ Ọlọ́run: Ìhìn Rere Jésù Krístì, kí àwọn tí ó ti sọnù lè rí ọ̀nà padà sí ilé Ìfẹ́.
Life Contents:
Àwọn ìjíròrò olóòtítọ́, tí ó gbé ẹsẹ̀ lé Ìwé Mímọ́, nípa ìdánimọ̀, àjọṣepọ̀, ète ìwàláàyè, àṣà, àti àwọn ọ̀ràn ojoojúmọ́.
Wisdom from the Holy Spirit:
Ìṣírí, ìjìnlẹ̀ òye, àti àwọn àṣàrò tí ó gbé ẹsẹ̀ lé Ìwé Mímọ́ láti fún ìgbàgbọ́ yín lókun àti láti mú kí ìrìn yín pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára.
Àdúrà mi ni kí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ pọdkásitì yìí ràn yín lọ́wọ́ láti pàdé Jésù, láti dàgbà nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, láti gbé nípa òtítọ́ Rẹ̀, àti láti rí ète tí Ó ní fún ìgbésí ayé yín.
Ẹ káàbọ̀ sí Life with Tioluwani.
Ẹ jẹ́ kí a dàgbà nínú Krístì, kí a tọ́ ìgbésí ayé wa sọ́nà pẹ̀lú ọgbọ́n, kí a sì lépa ète Ọlọ́run pọ̀.
YORÙBÁ VERSION
This Yoruba version of the episode was translated and recorded by Pastor Adetola Goodman.
We are grateful for her contribution and for helping us bring this message of light and love to more people.
Ẹ ṣé púpọ̀, Pastor Adetola Goodman, fún ríràn wá lọ́wọ́ láti mú ìmọ́lẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i. ❤️